01 December, 2010

Odun n lo sopin

O ti to ijo meta ti mo tin ronu arojinle lori Pataki at maa se asaro ni ede abinibi mi.
Ti mo ba ma je omo Yoruba rere, mo ma wipe Yoruba ni ede abinibi mi. Amo sa, eede Geesi ni afi to mi dagba. Eede geesi ni awon Oluko mi ile-iwe alakobere ati ile iwe giga lo lati fi ko wa ni eko ti o ye koo ro. Igbamiran ewe, ti mo ba roo sa, o jo pe eede Geesi ni ede abinibi mi.

Asaro mi je yo lati inu ibeere leyin ibeere ti awon alawo funfun ma beere wipe bawo ni awa alawo dudu omo Nigeria se mo oyinbo so paapa julo awon alawo funfun to sese nko eede geesi. Mi o lero sipe eyin oluka mi ko ni se alaimo nkan ti mo n so.

Leyin atotunu wipe eya bi ogorun meji le ni aadota lon be ni orile eede mi, o ma n se bi eni pe won a mi ri, sugbon alaye mi o ye won to be je be.

Eni ni ojo kini, osu kejila odun 2010. Nipari osu yi, odun yi a tun dopin niyen. Asiko odun yi ni oluwa re ma n ro nu pe kini mo ti fi igbesi aye mi se ninu odun to koja yi. Kini mo fe fi igbesi aye mi se ninu odun to n bo. Ojo ori mi ma n le si…mi o gbodo wa lee le laarin awon egbe mi…iru eero ti o maa ma dalu ara won niyen ninu okan oluwa re niyen.

Ninu odun yi, orisirisi nkan lo ti sele ninu igbesi aye mi ati t’orile ede mi. Lara awon nkan ti mo ti ko ni wipe o dun lati bu enu ate lu elomiran wipe won see daada to amo sa ki ni Oluwa re na ti gbe se ti a fi wa sope o lenu ati soro.
Eni ti o ba ti de ipo alase ko le mo iru ina ti o n koju awon ti o wa ni lori oye.

Orile ede mi Nigeria o ni laelae yi pada. Ko si ilu ibomiran ti mo le so pe mo ti wa ju ikan yen na ti mo ni lo.
Olorun a tun bo ma bukun orile ede mi, awon omo Nigeria rere, awaon ebi, ore mi ati ojulumo mi. Ki Olorun bukun fun gbogbo wa o. Amin.

No comments: